02/01/2021
BÀBÁ ẸLẸ̀YẸ
Baba olówó kan wa ti gbogbo eniyan mo si baba ẹlẹyẹ. Baba ọlọ́rọ̀ yii ni ẹyẹ kan to n si lagbala re lọ́jọ́ pípẹ́ sẹ́yìn. Baba yii ki i fi oro eye yii seré rara. Opo igba ni oro eye yii n da ija sile laarin baba yii ati ebi re.
Lojo kan, akọbi baba lo ba baba re ni ìdajì kutu, o be baba pe ki won gbe eye to n fa isonu yii kuro ninu ogba. O so aheso ọ̀rọ̀ ti eti oun n gbo nigboro fun baba re. Baba fun omo re lesi:
"Akanbi, ma da awon ọlōtẹte lohun, ola ti mo ni lo n bi won ninu. Ona ola mi sokunkun loju won lo je ki won ma a so isokuso kiri. Omo ola, agunbaje kò lódó, enu lasan l'odo won. Akanbi, gbera dide ki o gba ibi ise re lo." Akanbi dupe lowo baba re, o si gba ibi ise re lo.
Esi ti baba Akanbi fun un ko te e lọ́run to lórí ẹyẹ tí baba rẹ̀ ń sìn yìí. Omokunrin yii ko duro, o tun gba odo iya re lo boya yóò tu isu dele ikoko idi ti omo araye kò fi pe baba oun loruko ọmọ bibi inu re mo, to je orúkọ ẹyẹ ni won fi n pe won. Iya Akanbi naa fi Olorun bura pe oun ko mo idi ti ọkọ oun fi n sin ẹyẹ isọnu náà. . Iya je ko ye omo re pe oun o ka iwa palapala mo baba re lowo ri. Ó rọ ọmọ rẹ̀ pé Ki o ma feti si ọ̀rọ̀ awon elegan.
Lowuro kutukutu ojo kan, baba ẹlẹyẹ pe gbogbo awon omo re si gbagede. O salaye fun won ohun to faa ti oun fi n sin eye:
"Eyin omo o mi, Adaniwaye ko ni ṣe yín ní alatulẹ̀jẹ. Gbogbo yin le o ni laari. Kekere ni ọrọ̀ ti mo ni yóò je ninu eyi ti Eledua yóò se fun yin. Ìṣẹ́ kò lóògùn mìíràn to ju isẹ́ asekára lo. N o dọgbọn sówó. Isẹ́ ọwọ mi ni mo n jẹ . Lori ọ̀rọ̀ ẹyẹ ti mo n sin, hmmmm! Baba kan lo fi ọ̀rọ̀ ẹyẹ se ikilo fun mi nigba ti ọwọ mi ṣẹ̀ṣẹ̀ n ji s'owo. Nigba naa lóhùn un,, ọtí amutakiti lójoojúmọ́ ni. Ọmọdé ko kúkú mọ pe àárọ̀ n dọ̀sán. Awon to gbọn ju wa lọ to ye ko si wa leti ko lówó lọ́wọ́. Àbá wo ni talaka fe da niwaju eni ti aje n ba je? Awon to lówó lọ́wọ́ jù wá lọ ko ba wa sootó ọ̀rọ̀ nitori won o fe ki a jo wa nipo kan naa.
Ní àsìkò kan, ise aje gbé mi lo si ìlú Àlejòlowó. Eyin ọmọ mi, mo rí nǹkan kàyéfì ni ilu yìí. Tonile, talejo ilu Alejolowo lo ri taje ṣe. Kò sí tálákà nínú gbogbo àwọn olùgbé ìlú yìí. Leyin Ìjẹ̀bú ati Ègbá, n o tun ti i ri ilu ti olówó ti po to Alejolowo ri. Ni irole ọjọ ti mo kọ́kọ́ de ilu Alejolowo, mo gba ilé emu lo gẹ́gẹ́ bi ìse è mi. Gbogbo awon to n mẹmu ati iya elemu pelu n fi mi se iran wo nígbà tí mo ń náwó bí elẹ́dà. Won o ti i ri eni to n nawo bi temi rí nínú ìlú yìí. Lojo kejì ti mo de ilé elemu, mo ba baba olooraye kan nibe. Bi baba yii se f'oju kan mi lo sare dide, bàbá yìí fa mi lo si kọ̀rọ̀ kan tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé ẹmu. Baba beere omo ilu ti mo n se, mo daruko ilu ti mo ti wa. Baba kilo fun mi pe ki n ma f'ọwọ́ pada ofin ilu wọn loju. Wọ́n ni ọba ìlú Alejolowo ko gbọ́dọ̀ gbọ́ pe ẹnikan n na ina apa. Baba fi itan Ajénifújà to na ìná àpà nígbà kan balè lerefee. . Ajenifuja kan naa lo te ilu Alejolowo do. Baba ni Ajénifújà lówó lowo bi sèkèrè. Kaka ko fi owo re de nnkan mole, afefeyeye lo n fowo se kiri. Nigba to ya, owo tan pátápátá lọ́wọ́, arakunrin yii ko ri aje mu se fuja mo. Igba ti nnkan doju ogongo, Ajénifújà mu ookan kun eeje, o gboko awo lo. Babalawo ni ọrọ Ajénifújà o gbẹbọ béèni ko gbetutu. Won ni kí Ajenifuja wá bí yóò ṣe rí ẹyẹ ooyẹ mu. Ti o ba ti mu eye yii, ko fo oju rẹ méjèèjì jeeji. Leyin eyii, ko kan ilé rébété ti ẹyẹ yii yo ma a gbé fún un. Iya kan o gbọ́dọ̀ je ẹyẹ yii. Ajénifújà se bi alágbigba se wi.
Baba yii so fun mi pe Ajénifújà kò kọ́kọ́ ka ọ̀rọ̀ awo kun nitori ibi to foju si, ona o gba be. Owó ojiji lo n fe ki awo se fun òun. Lèyín o rẹyìn, Ajénifújà mú ẹyẹ looyẹ, o fo ẹyẹ loju, o n fun un lonje pẹ̀lú ṣùgbọ́n ko kan ilé fun ẹyẹ yii.
Ni igba kan, Ajénifújà lọ sí irinajo, awon ẹbi rẹ e ko ranti fún ẹyẹ yìí ni itoju tó péye bí ti olówó rẹ. Bi ẹyẹ se fo lo ni yii.
Nigba ti Ajénifújà de lati irinajo, ko ba ẹyẹ oko nile mo. O wa gbogbo ayika boya yoo ri ẹyẹ yii sugbon ko rii. Ajenifuja ro pe ko ye kí eyeye fo jínna nitori afoju ni. Igba ti Ajénifújà ko ri eye, o ko itiju ta, o tun gbale awo lọ. O salaye fun baba bí ìṣù ṣe kú, ati bí ọ̀be ṣe bẹẹ.
Alagbigba so fun Ajénifújà pe apejuwe lasan lóun se fun un. Akoko, Ooyẹ ẹyẹ ni iṣẹ́ owó sise, èyí to ni wàhálà pupọ. Gbéwiri papa n se akọ ise ko to kólé onile. Eleekeji èwè, ko si bi owó se le e pọ to, ti a o ba toju re daadaa, o seese kò tán. Ajénifújà gbagbe pe oju ẹyẹ lo fọ , ìyé ẹyẹ ò re. Oju ko lẹyẹ fi n fo, ìyé ni. Lákòótán, baba so fun mi pe, afọ́jú ẹyẹ lowó, ko si ibi ti o le e ba si. Eyi lo je ki Yoruba gbagbọ pe owó ko ni iran.
Bi mo se gbọ́ ọ̀rọ̀ yii lenu baba tan, jẹbẹtẹ gb'ọmọ le mi lọ́wọ́. Ọ̀rọ̀ yii wọ mi lakinyẹmi ara. Nigba ti mo dele, mo sun orun mẹta ti omokunrin n sun. Mo si pinnu pe bi ina mi ba ti n jo, n o ma a fi jo nnkan logan ni.
Ẹyin ọmọ mi, loju to mo loni, ta ni baba yin je ní gbèsè? Eni to ba wọlé e mi, bi o ba je eni to wáá ya, a je ẹni to yóò san. N o fi se igberaga, ọ̀rọ̀ lo kó moko moro wá. Ẹyẹ ti mo n sìn, mo fi n ranti baba ti Eledua ran si mi ni. Olóore eni ki i se dandan ko je eni to gbówó tabua fun ni gẹ́gẹ́ bi irori ẹyin ọdọ iwoyi, ẹni to ba gbani ni ìmọ̀ràn, ti ìmọ̀ràn yii seni lanfaani, olóore eni ni. Se ohun to ruju ti mólè kedere? "
Inu awon ọmọ baba ẹlẹyẹ dun fun ọ̀rọ̀ isiti ti baba fi bo won.
A kú ọdún, a kú ìyèdún, ọdún yóò yabo fún wa.